Announcing the Transition of Araba Oyewusi Amoo Fakayode

27/06/2020 17:09
Eríwo Yà! Eríwo Yà!! Eríwo Yà!!!
Erin wó
Àjànàkú sùn bí òkè
Lójú Olúgbọ̀n, bí i kí Orò má lọ
Lójú Arẹ̀ṣà, bí i kí Orò má lọ
Agbe dáró tán, Agbe ń lọ
Àlùkò kosùn tán, Àlùkò ń relé
Oyèwùsì Àmọ̀ó Fákáyọ̀dé ṣe tán, ó ń relé Ifẹ̀
An elephant has fallen
Left alone to Olúgbọ́n, it was as if Orò should not disappear
In the mind of Arẹ̀ṣà, it was as if Orò should stay till eternity
The blue touraco bird has finished making dye and gone
The purple touraco bird after making the camwood has dispersed
Oyèwùsì Àmọ̀ó Fákáyodé has finished his assignment in this terrestrial space, he is now transitioning to the celestial realm
With gratitude to Olódùmarè for the life well spent, we announce the transition of our father, the Patriarch of the Oyèkúnlé family of Oníbùdó Compound, Ìbàdàn, the Baálẹ̀ of Àlàdé Town, Ìbàdàn and the Àràbà/Olú-Ìṣẹ̀ṣe of Ìbàdàn land who joined the ancestors today Thursday, 28th November, 2019 around 11:30 am after 18 hours illness at the ripe age of 105.
Ẹlẹ́yẹlé
Aládìyẹ
Àmọ̀ó tí di awo ilẹ̀ mìíràn
Both sellers and buyers of pigeons
Both sellers and buyers of fowls
Àmọ̀ó has become priest in another realm
Kò pé òun ò ṣe mọ́
Ikú ló yọwọ́ rẹ̀ nínú àwo
Àgbà Ìṣògbó fọwọ́ okùn lélẹ̀ o
He did not withdraw consciously
It was death who removed his hands from the plate
An elderly priest has laid down his hand decorated with okùn beads
Burial and funeral rites will take place on Friday, 13th December, 2019.
Signed:
Fayemi Fatunde Fakayode
For the family