Èjìògúndá/Ògúndá méjì (Èjì òkò)
OGUNDA MEJI
1.
Kanranjangban Awo inu igbo
A difa folomo afeyinti jogbon obi
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ki n to feyin ti jogboon obi mi tan
Igba ire gbogbo a wonu ile de
Kanranjangban Awo inu igbo
Cast Ifa for he-who-rests-his-back –on-the-wall-to-eat-thirty-kolanuts
He was advised to make ebo
He complied
Before I rest my back on the wall to eat my thirty kola nuts
Plenty fortune will surely come to me
2.
Igi lgbo ni selegbe leyin igbo
Igi odan ni selegbe leyin odan
A difa fun Oridagogo ti n lo ree naja Oloye
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
E ma na mi mo legbe leyin
Agogo ma lonigbija Orisa.
The trees in the forest are the supporters of the forest
The trees in the savannah are the supporters of the savannah
Ifa revelation to Oridagogo when going to the market of Oloye
He was advised to make ebo
He complied
Do not beat me, I have supporters
The gongs are the supporters of Orisa
3.
Abemole eekan aboju regunregun
A difa fooyi okoko ti n sunkun omo rode Ipo
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Ooyi rogun o bogun
Ooyi rogbon o bogbon
Eyin o mo pogun omo o to Ooyi?
Abemole eekan aboju regunregun
Cast Ifa for Ooyi Okoko when going to the city of Ipo in order to become a parent
He was advised to make ebo
He complied
Ooyi sacrificed twenty and begot twenty children
Ooyi sacrificed thirty and begot thirty children
Do not you know that twenty children are not enough for ooyi?
4.
Omi yinrinyinrin lomi agbada
Ewe oparun ni sikiti moparun leyin
A difa fun Kaore ti n lo ree ba won mule lailoko
Ebo ni won ni ko se
O si gbebo nibe o rubo
Igba ti e gbo pe mo la le wa ba mi
Emi Kaore ti e ti leyin o ni wa ba
Igba ti e gbo pe mo la le wa ba mi.
The water inside a broken pot is but little
The leaves of the bamboo tree stick tightly to the bamboo’s neck
Ifa revelation to Kaore when going to acquire a portion of land without a hoe
He was advised to make ebo
He complied
It is because you heard of my affluence that you have come to me
I, Kaore, who you have vowed never to come to
It is because you heard of my affluence that you have come to me