Èjìọ̀wọ́nrín/Ọ̀wọ́nrín méjì (Èjì ọ̀wọ̀n)
EJIOWONRIN
(1)
Oju oro ko roja ina
Eka legbe ewu
A difa fun Owiwi
To n lo ree gba aya Ogbigbi oloja eye
Owiwi o de
Eye ajoru
Ti a ba ri o losan-an
O deye alegba
Pond weed does not transact with fire
Shoulder is the anchor for cloth
Ifa revelation to Owiwi (Owl)
Who wanted to snatch the wife of Ogbigbi, a chief among
the birds
Here comes owiwi (Owl)
The bird which goes out only in the night
If we see you during the day
You will be subjected to unanimous disgrace
(Gbogbo eye lo ni ife owiwi ti won si n fun lowo. Ogbigbi naa je eye to niyi. Ogbigbi ni aya to rewa ti gbogbo eye nifee. Laitele ikilo ifa, owiwi gba iyawo ogbigbi. Gbogbo eye to korira iwa ti owiwi hu. Won ni ki o da aya pada fun alaya. Owiwi ko, dipo eyi, o fun obinrin naa loyun. Awon eye ba se ipade lati fi owiwi se esin nibikibi ti won ba ti ri i. Won fe lati ja a si ihooho loju gbogbo aye takotabo. Bee ni, owiwi ko ri eye kan soso pon leyin re. Oun naa ba wa ona abayo, o si mo pe ohun ti oun le se nip e ki oun mase jade ni osan ayafi oru. Nigba ti awon eye ko ri I ko jade osan mo, ni eekookan, won a kora won jo lo si ile re lati doju ti I, won a si maa ko orin to wa ni ila merin to gbeyin ese ifa naa, sugbon owiwi ko je yoju si won. Lati igba naa ni owiwi ti di eye ti kii jade ni osan ayafi oru.
Owiwi (Owl) was a very popular bird among his colleagues, every one of them liked him and accorded him befitting honor. Ogbigbi ( ) was another bird who was also prestigious. He was also accorded befitting honor. Both birds were contemporaries and bosom friends had a very beautiful wife who almost every bird admired. Ifa tells us that owiwi tried all her best to woo the woman despite the advice from ifa during consultation that he should not snatch another person'swife. Owiwi snatched the wife successfully but to his own detriment. After the deed, almost all the birds had sympathy for Ogbigbi. They gathered together and told Owiwi to return the wife. He refused and impregnated the woman, his friend's wife. Later, all the birds ganged together and decided to disgrace Owiwi anywhere he was caught. They planned to strip him naked in the presence of every bird, both male and female. In fact, no single bird supported Owiwi. Therefore, he decided not to come out during the day again but in the night. At interval, the bird would go to his house in an attempt to disgrace him. They would be there singing the song in the last four lines of the verse, but owiwi would never come out. Since then, owiwi has become a bird that comes out only in the night).
(2)
Ogba orogun ni mo ri
N ko ri ogba iyako
A difa fun Akitinpa
To n lo ree diro mo Ooro lorun
Emi-yee Awo Ooro
A difa fun Ooro
Akitinpa lo mama ku o
Ooro a si gbele
Ooro ti sebo Emi-yee
Rivalry from a co-wife is normal
Rivalry from the mother-in-law is abnormal
Ifa revelation to Akitinpa
Who aws making life unbearable for Ooro
Emi-yee the Ifa priest of Ooro
Divine Ifa for Ooro
It is Akitinpa who will die
Ooro will still be alive
Ooro has made the ebo recommended by Emi-yee
Akitinpa n mu aye nira fun Ooro, iyawo omo re. Ko je ko ni ibale okan rara.Ifa kilo fun Akitinpa sugbon ko fe, Nse lo n wa isubu ooro ni gbogbo igba. Oore da ifa, a si so fun un pe ki o ru ebo pelu okete kan, akukodie kan, ada kan, owo ati epo pupa. O ru ebo naa. Ebo oun da debi pe ooro ko mo ibi ti isegun ti wa. Ko sanna kankan lati pa Akitinpa tabi wa isubu re. lojiji, Akitinpa ni ija pelu elomiran to tun buru ju oun funra re lo. E ni naa si doju re dele patapata. Leyin eyi ni a bo ajaga buburu gbogbo kuro lara ooro.
Akitinpa was making life uneasy for Ooro her daughter – in –law. She did not let her have peace of mind at all. Ifa warned Akitinpa but she heeded not to the advice. She looked for Ooro' demise every moment. Ooro consulted ifa and her Babalawo told her to make sacrifice with a giant rat (okete), a cock, a cutlass, money and palmoil. She complied. The sacrifice was effective that she did not make attempt to kill not to destroy Akitinpa. Suddenly, Akitinpa had quarrel with somebody who happened to be more aggressive than Akitinpa. The person saw to her demise totally and Ooro was relieved of the burden.
3.
Aride werewere seke
Abopa oje kitisan
Omo tuntun abatewo rogbarogba
A difa fun anasin aya Olofin
Lojo to n moju ekun sogbere omo
Ebo ni won ni ko se
O gbebo nibe o rubo
Igba ti aja n bi
Ni Anasin n bi
Owindinwindin!
Aja lo komo dajule wa
He who has plenty brass to use as …
One with strong lead walking stick
New born baby with smoothly soft palms
Cast Ifa for Anasin, the wife of Olofin
When she was longing for children
She was advised to make ebo
She complied
When the dog started putting to bed
Anasin also started putting to bed
Plenty children!
It is the dog that ushered children into our house
4.
Olobonhunbonhun lo wonu ikoko odu
O fi owo mejeeji da gbedu idi
O dun gbamuraja gbamuraja
A difa fun Ojokoromifo omo Olofin
O n sebo re ni Ikoko
O n sebo re ni Ibaba
Ko juba Baba
Ko juba Yeye
Ko juba Oluwo
Ko juba Ojugbona
Ko juba Iyanifa
Ko juba Apetebi aya Orunmila
Iba Baba
Iba Yeye
Iba Oluwo
Iba Ojugbona
Iba Paripa
Iba Adaso mo muro
Olowo gba a laye
Ebora gba a lorun
Iwerenje parakun Obarisa
Ayafi bi mo da se
Koro ma saigba
Baba ba mi se e
Asefin asegba
Iya ba mi see
Asefin asegba
Ori ba mi se e
Asefin asegba
Ikin ba mi see
Asefin asegba
A scrab beetle flied into a big pot
Using its two wings to beat its buttocks as drum
It hummed incessantly
Cast Ifa for Ojukoromifo, the child of Olofin
While making his offering in concealment
While performing his sacrifice in secret
He gave no response to his father
He gave no response to his mother
He gave no response to his Oluwo
He gave no response to his Ojugbona
He gave no response to his Iyanfa
Reverence to my father
Reverence to my mother
Reverence to my Oluwo
Reverence to my Ojugbona
Reverence to my Iyanifa
Reverence to Apetebi, wife of Orunmila
Reverence to paripa
Reverence to Adaso-ma-muro
Lord! Accept it on Earth
Deity! Accept it is Heaven
Iwerenjeje trailing shrub of the Arch-Deity
Unless i do without reverence
My rituals will never be unacceptable
Aid me to accomplish it my father
Meticulous aid
Aid me to accomplish it my mother
Meticulous aid
Aid me to accomplish it my Ori
Meticulous aid
Aid me to accomplish it my Ikin
Meticulous aid