Èjììròsùn/Ìròsùn méjì (Olósùn méjì)
EJIIROSUN
(1)
Agilinti ni gboko ni pari
Konko ni gbodo ta piti
Alantakun ni gboko ni ranwu oginniginni
A difa fun Oyigi
Ti yoo bi Ela lomo
Iku to loun o pa oyigi
Ela omo re ni ko je o
Gbogbo ajogun ibi to ni awon yoo se Oyigi
Ela, omo re ni ko je o
It is agilinti that stays in the farm to get bald
It is toad that lives in the river to jump here and there
It is spider that stays in the farm to spine tread
Cast Ifa for Oyigi
Who gave birth to Ela
The death that would have killed Oyigi
Ela, her child was the one that prevented it
All evil forces that would have harmed Oyigi
Ela, her child was the one that prevented them
2.
A dako, a da roko
A dako, a da rodo
Ada-wa-mu_fooro jangan
A difa fun Eleko Idere
Ti yoo loro kale o to le
Eleko Idere
Sebi o loo jere?
O roso dudu
O roso pupa
O fayinrin gbaja
O fapoti tidi
O le kenka
Eleko Idere
Sebi o lo o jere
Ifa mase je kale oro o le mi
We buy corn pap
For taking to the farm
We buy corn pap
For taking to the river
Buying of pap squeeze inside water for drinking
Ifa revelation to the pap seller of idere
Who would became rich before old age
The pap seller of the city of idere
But, you still complain of not making profit
You put on black clothYou put on red cloth
You tie multi-coloured robe
You sit on a stool
You pose majestically
The pap seller of the city of idere
You still complain of not making profit
Ifa, do not let my wealth come belatedly.
3.
Igba epo lo pon rerere
Bi eni pe yoo joni lowo
Bee ni ko le joni lowo
Lasan lolosun meji soju lasalasa
Bi eni o loro ninu
Irosun meji ko nika ninu
A difa fun Orunmila
Lojo ti Baba n jaye lile
Alade fi elede rubo
Gbede
Lara o maa de wa lo
The calabash of palm oil is very red
As if it will scald one’s hand
But it cannot scald one’s hand
Olosunmeji ordinarily looks hard
Like somebody who arbours wickedness
Irosun meji does not possess wicked attribute
Cast ifa for Orunmila
When he was experiencing difficulty in life
Alade has sacrifice pig
Comfortable!
Our lives will
4.
Eje logbo lo gbekun doyun
A difa fun Ibiolatiwa
Ti se omo onidere
Lojo to fe joye ile baba re
Ebo ni won ni o se
Riru ebo ni gbeni
Eru atatetu ni i da ladaju
Ogbun eyiku o
O wa dogbun eyiye.
Watery blood stays inside the stomach and becomes pregnancy
Ifa declaration for Ibiolatiwa
The one that was a child of Onidere
When he wanted to mount the throne of his father’s house
He was advised to offer sacrifice
Offering of sacrifice is what favours one
Quick performance of rituals in always efficacious
The pit inside which one fell and died
It then turned to the pit of survival.